Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 22:22-31 BIBELI MIMỌ (BM)

22. N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi;láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́:

23. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín!Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un,ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli!

24. Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́;kò sì ṣá wọn tì,bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn,ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é.

25. Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan;n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA.

26. Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó;àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín!Kí ẹ̀mí wọn ó gùn!

27. Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWAwọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀;gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdèni yóo sì júbà níwájú rẹ̀.

28. Nítorí OLUWA ló ni ìjọba,òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.

29. Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀;gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀,àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè.

30. Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín;àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀.

31. Wọn óo máa kéde ìgbàlà rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,pé, “OLUWA ló ṣe é.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 22