Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 22:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, má jìnnà sí mi!Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, ṣe gírí láti ràn mí lọ́wọ́!

20. Gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ idà,gbà mí lọ́wọ́ àwọn ajá!

21. Já mi gbà kúrò lẹ́nu kinniun nnìgbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwo ẹhànnà mààlúù!

22. N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi;láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́:

23. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín!Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un,ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli!

24. Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́;kò sì ṣá wọn tì,bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn,ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é.

25. Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan;n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA.

26. Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó;àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín!Kí ẹ̀mí wọn ó gùn!

27. Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWAwọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀;gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdèni yóo sì júbà níwájú rẹ̀.

28. Nítorí OLUWA ló ni ìjọba,òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.

29. Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀;gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀,àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè.

30. Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín;àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀.

31. Wọn óo máa kéde ìgbàlà rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,pé, “OLUWA ló ṣe é.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 22