Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 22:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀,tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi,kí o sì ràn mí lọ́wọ́?

2. Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án,ṣugbọn o ò dáhùn;mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́.

3. Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́,o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́.

4. Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé;wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n.

5. Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n;ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n.

6. Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan;ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

7. Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi;wọ́n sì ń mi orí pé,

8. “Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́;kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là,ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!”

9. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi;ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 22