Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 22:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀,tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi,kí o sì ràn mí lọ́wọ́?

2. Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án,ṣugbọn o ò dáhùn;mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́.

3. Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́,o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́.

4. Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé;wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n.

5. Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n;ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n.

6. Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan;ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

7. Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi;wọ́n sì ń mi orí pé,

8. “Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́;kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là,ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!”

9. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi;ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú.

10. Ìwọ ni wọ́n bí mi lé lọ́wọ́;ìwọ ni Ọlọrun miláti ìgbà tí ìyá mi ti bí mi.

11. Má jìnnà sí mi,nítorí pé ìyọnu wà nítòsí,kò sì sí ẹni tí yóo ràn mí lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 22