Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 21:4-13 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un,àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé.

5. Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́;o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀.

6. Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae;o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀.

7. Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA;a kò ní ṣí i ní ipò pada,nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀.

8. Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ.

9. O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn.OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀;iná yóo sì jó wọn ní àjórun.

10. O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé,o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan.

11. Bí wọn bá gbèrò ibi sí ọ,tí wọ́n sì pète ìkà, wọn kò ní lè ṣe é.

12. Nítorí pé o óo lé wọn sá;nígbà tí o bá fi ọfà rẹ sun ojú wọn.

13. A gbé ọ ga, nítorí agbára rẹ, OLUWA!A óo máa kọrin, a óo sì máa yin agbára rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 21