Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 21:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọba ń yọ̀ nítorí agbára rẹ, OLUWA;inú rẹ̀ ń dùn lọpọlọpọ nítorí ríràn tí o ràn án lọ́wọ́!

2. O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́,o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú.

3. O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀;o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí.

4. Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un,àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé.

5. Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́;o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀.

6. Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae;o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀.

7. Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA;a kò ní ṣí i ní ipò pada,nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀.

8. Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ.

9. O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn.OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀;iná yóo sì jó wọn ní àjórun.

10. O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé,o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan.

11. Bí wọn bá gbèrò ibi sí ọ,tí wọ́n sì pète ìkà, wọn kò ní lè ṣe é.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 21