Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 2:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba;Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi,lónìí ni mo bí ọ.

8. Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè,gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ.

9. Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn,o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”

10. Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀.

11. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA,ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì.

12. Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú,kí ó má baà pa yín run lójijì;nítorí a máa yára bínú.Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 2