Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 2:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfùtí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán?

2. Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀,wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.

3. Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá jákí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.”

4. Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín;OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.

5. Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀,yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀,

6. Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ,ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.”

7. N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba;Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi,lónìí ni mo bí ọ.

8. Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè,gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ.

9. Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn,o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”

10. Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀.

11. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA,ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 2