Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 19:8-14 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú.

9. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.

10. Wọ́n wuni ju wúrà lọ,àní ju ojúlówó wúrà lọ;wọ́n sì dùn ju oyin,àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ.

11. Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀,èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́.

12. Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀?Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi.

13. Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá;má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi.Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́,n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mijẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 19