Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 19:6-10 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá,a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji;kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀.

7. Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí;àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

8. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú.

9. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.

10. Wọ́n wuni ju wúrà lọ,àní ju ojúlówó wúrà lọ;wọ́n sì dùn ju oyin,àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 19