Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 19:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun,òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

2. Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbàòru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn.

3. Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn;

4. sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já,ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé.Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run,

5. tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀,ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje.

6. Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá,a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji;kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀.

7. Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí;àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

8. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú.

9. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.

10. Wọ́n wuni ju wúrà lọ,àní ju ojúlówó wúrà lọ;wọ́n sì dùn ju oyin,àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 19