Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 18:47-50 BIBELI MIMỌ (BM)

47. Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi,tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi;

48. Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ;ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi.

49. Nítorí náà ni èmi ó ṣe máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, OLUWA,èmi ó sì máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.

50. Ó fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ han ẹni àmì òróró rẹ̀,àní Dafidi ati ìrandíran rẹ̀ títí lae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 18