Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 18:40-48 BIBELI MIMỌ (BM)

40. O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi,mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.

41. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n,wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

42. Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ,mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù.

43. O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan,o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè;àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí.

44. Bí wọ́n bá ti gbúròó mi ni wọ́n ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu;àwọn àjèjì ń fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba, wọ́n ń wá ojurere mi.

45. Àyà pá àwọn àlejò,wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.

46. OLUWA wà láàyè! Ẹni ìyìn ni àpáta mi!Ẹni àgbéga ni Ọlọrun ìgbàlà mi!

47. Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi,tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi;

48. Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ;ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 18