Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 18:27-43 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là,ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.

28. Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn,OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.

29. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo lè run ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun,àní, pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun mi, mo lè fo odi ìlú.

30. Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé,pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA;òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í.

31. Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA?Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa?

32. Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí,tí ó sì mú ọ̀nà mi pé.

33. Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí.

34. Ó kọ́ mi ní ogun jíjàtóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ.

35. O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ,ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró,ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá.

36. O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi,n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́.

37. Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n,n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run.

38. Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde,wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi.

39. O gbé agbára ogun wọ̀ mí;o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.

40. O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi,mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.

41. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n,wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

42. Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ,mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù.

43. O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan,o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè;àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 18