Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 18:19-34 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè,ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi.

20. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè.

21. Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́,n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.

22. Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé,n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀.

23. Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀,mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀.

24. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀.

25. Ò máa dúró ti àwọn tí ó dúró tì ọ́,ò sì máa ṣe àṣepé fún àwọn tí ó pé;

26. mímọ́ ni ọ́ sí àwọn tí ọkàn wọn mọ́,ṣugbọn àwọn alárèékérekè ni o fi ọgbọ́n tayọ.

27. Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là,ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.

28. Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn,OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.

29. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo lè run ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun,àní, pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun mi, mo lè fo odi ìlú.

30. Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé,pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA;òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í.

31. Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA?Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa?

32. Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí,tí ó sì mú ọ̀nà mi pé.

33. Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí.

34. Ó kọ́ mi ní ogun jíjàtóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 18