Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 17:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbọ́ tèmi OLUWA, àre ni ẹjọ́ mi;fi ìtara gbọ́ igbe mi.Fetí sí adura mi nítorí kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu mi.

2. Jẹ́ kí ìdáláre mi ti ọ̀dọ̀ rẹ wá;kí o sì rí i pé ẹjọ́ mi tọ́.

3. Yẹ ọkàn mi wò; bẹ̀ mí wò lóru.Dán mi wò, o kò ní rí ohun burúkú kan;n kò ní fi ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀.

4. Nítorí ohun tí o wí nípa èrè iṣẹ́ ọwọ́ eniyan,mo ti yàgò fún àwọn oníwà ipá.

5. Mò ń tọ ọ̀nà rẹ tààrà;ẹsẹ̀ mi kò sì yọ̀.

6. Mo ké pè ọ́, dájúdájú ìwọ Ọlọrun yóo dá mi lóhùn,dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

7. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà ìyanu,fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọkúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì wọ́n.

8. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú,dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ;

9. lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí,àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 17