Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 150:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ yin OLUWA!Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀;ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára.

2. Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀;ẹ yìn ín nítorí pé ó tóbi pupọ.

3. Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín;ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín.

4. Ẹ fi ìlù ati ijó yìn ín;ẹ fi gòjé ati dùùrù yìn ín.

5. Ẹ fi aro olóhùn òkè yìn ín;ẹ fi aro olóhùn gooro yìn ín.

6. Kí gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 150