Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 149:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀,a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.

5. Kí àwọn olódodo máa ṣògo ninu ọlá;kí wọ́n máa kọrin ayọ̀ lórí ibùsùn wọn.

6. Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun;kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn,

7. láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà;

8. láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn,ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn;

9. láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀.Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí.Ẹ yin OLUWA!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 149