Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 148:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ yin OLUWA!Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,ẹ yìn ín lókè ọ̀run.

2. Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀;ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀.

3. Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá;ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn.

4. Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ;yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run.

5. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA,nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn.

6. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae;ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá.

7. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi;

8. iná ati yìnyín, ati ìrì dídì,ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ.

9. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké,ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari;

10. ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn,ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò.

11. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè,ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé;

12. ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge,ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà.

13. Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA,nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù;ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ.

14. Ó ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára,ó sì fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ ní ìyìn;ó fún àwọn eniyan Israẹli, tí ó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ̀.Ẹ yin OLUWA!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 148