Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 147:12-20 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni!

13. Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ.

14. Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ,ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó.

15. Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá.

16. Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú,ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.

17. Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀?

18. Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́,ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.

19. Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu,ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli.

20. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí,wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀.Ẹ yin OLUWA!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 147