Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 146:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ yin OLUWA!Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.

2. N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé;n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè.

3. Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè;eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn.

4. Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀,ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé.

5. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀.

6. Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé,òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae,

7. ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára;tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ,OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀.

8. A máa la ojú àwọn afọ́jú,a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró;ó fẹ́ràn àwọn olódodo.

9. OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò,òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba,ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú.

10. OLUWA yóo jọba títí lae,Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran.Ẹ yin OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 146