Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 145:7-21 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó,wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ.

8. Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni;kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.

9. OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan,àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá.

10. OLUWA, gbogbo ohun tí o dá ni yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,àwọn eniyan mímọ́ rẹ yóo sì máa yìn ọ́.

11. Wọn óo máa ròyìn ògo ìjọba rẹ,wọn óo sì máa sọ nípa agbára rẹ,

12. láti mú àwọn eniyan mọ agbára rẹ,ati ẹwà ògo ìjọba rẹ.

13. Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ,yóo sì máa wà láti ìran dé ìran.Olóòótọ́ ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀,olóore ọ̀fẹ́ sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.

14. OLUWA gbé gbogbo àwọn tí ń ṣubú lọ dìde,ó sì gbé gbogbo àwọn tí a tẹrí wọn ba nàró.

15. Ojú gbogbo eniyan ń wò ọ́,o sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò.

16. Ìwọ la ọwọ́ rẹ,o sì tẹ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè lọ́rùn.

17. Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀,aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.

18. OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é,àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn.

19. Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn;ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n.

20. OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí,ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run.

21. Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA;kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 145