Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 145:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi,n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae.

2. Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́,tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae.

3. OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ;àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀.

4. Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ,tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ.

5. Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ,ati iṣẹ́ ìyanu rẹ.

6. Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu,èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 145