Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 143:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, gbọ́ adura mi;fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi!Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.

2. Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́,nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ.

3. Ọ̀tá ti lé mi bá,ó ti lù mí bolẹ̀;ó jù mí sinu òkùnkùn,bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.

4. Nítorí náà ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì;ọkàn mi sì pòrúúruù.

5. Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe,mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

6. Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́;bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ,bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.

7. OLUWA, yára dá mi lóhùn!Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin!Má fara pamọ́ fún mi,kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú.

8. Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀,nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn,nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí.

9. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;ìwọ ni mo sá di.

10. Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi.Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 143