Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 140:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. OLUWA, má jẹ́ kí ọwọ́ àwọn eniyan burúkú tẹ ohun tí wọn ń wá;má jẹ́ kí èrò ọkàn wọn ṣẹ.

9. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ibi ẹnu àwọn tí ó yí mi kádà lé wọn lórí.

10. Jẹ́ kí ẹ̀yinná dà lé wọn lórí;jẹ́ kí wọn já sí kòtò, kí wọn má lè yọ.

11. Má jẹ́ kí abanijẹ́ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ náà;jẹ́ kí oníwà ipá ko àgbákò kíákíá.

12. Mo mọ̀ pé OLUWA yóo gba ọ̀ràn olùpọ́njú rò,yóo sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.

13. Dájúdájú, àwọn olódodo yóo máa fi ọpẹ́ fún ọ;àwọn olóòótọ́ yóo sì máa gbé níwájú rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 140