Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 14:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò sí.”Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn,kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere.

2. OLUWA bojú wo ilẹ̀, láti ọ̀run wá,ó wo àwọn ọmọ eniyan,láti mọ̀ bí àwọn kan bá wà tí wọ́n gbọ́n,tí wọn ń wá Ọlọrun.

3. Gbogbo wọn ti ṣìnà,gbogbo wọn pátá ni wọ́n sì ti bàjẹ́;kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,kò sí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo.

4. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,àwọn tí kì í ké pe OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 14