Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 138:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ,n óo sì máa yin orúkọ rẹ,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ,nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ.

3. Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn,o sì fún mi ní agbára kún agbára.

4. OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́,nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.

5. Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA,nítorí pé ògo OLUWA tóbi.

6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá,ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí,ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè.

7. Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú,sibẹ, o dá mi sí;o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi,o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí.

8. OLUWA yóo mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí mi,OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.Má kọ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sílẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 138