Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 137:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún,nígbà tí a ranti Sioni.

2. Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí,

3. nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùnti ní kí á kọrin fún àwọn.Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní,“Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.”

4. Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì?

5. Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.

6. Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi,bí n kò bá ranti rẹ,bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.

7. OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣenígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,tí wọn ń pariwo pé,“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”

8. Babiloni! Ìwọ apanirun!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ,fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 137