Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 136:18-24 BIBELI MIMỌ (BM)

18. ó sì pa àwọn ọba olókìkí,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

19. Sihoni ọba àwọn Amori,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

20. ati Ogu ọba Baṣani,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

21. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

22. ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

23. Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

24. ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 136