Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 136:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

3. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

4. Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

5. Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

6. ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

7. ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 136