Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 135:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run;ó pa àwọn ọba alágbára:

11. Sihoni ọba àwọn Amori,Ogu ọba Baṣani,ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani.

12. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀;ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn.

13. OLUWA, orúkọ rẹ yóo wà títí lae,òkìkí rẹ óo sì máa kàn títí ayé.

14. OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,yóo sì ṣàánú àwọn iranṣẹ rẹ̀.

15. Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn,iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.

16. Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran.

17. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn,bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn.

18. Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn,ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn.

19. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA,ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA!

20. Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA,ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín!

21. Ẹ yin OLUWA ní Sioni,ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu!Ẹ yin OLUWA!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 135