Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 130:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA!

2. OLUWA, gbóhùn mi,dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

3. Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀,ta ló lè yege?

4. Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà,kí á lè máa bẹ̀rù rẹ.

5. Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e,mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀.

6. Mò ń retí rẹ, OLUWA,ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ,àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.

7. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA!Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà,ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 130