Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 129:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi.Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,

2. “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi,sibẹ, wọn kò borí mi.”

3. Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn,gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko.

4. Ṣugbọn olódodo ni OLUWA,ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú.

5. Ojú yóo ti gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni,a óo lé wọn pada sẹ́yìn.

6. Wọn óo dàbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,tí kì í dàgbà kí ó tó gbẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 129