Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 128:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA,tí ó sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.

2. O óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,ayọ̀ ń bẹ fún ọ, yóo sì dára fún ọ.

3. Aya rẹ yóo dàbí àjàrà eléso pupọ ninu ilé rẹ;bí ọmọ tií yí igi olifi ká,ni àwọn ọmọ rẹ yóo yí tabili oúnjẹ rẹ ká.

4. Wò ó, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo kẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

5. Kí OLUWA bukun ọ láti Sioni!Kí o máa rí ire Jerusalẹmuní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

6. Kí o máa rí arọmọdọmọ rẹ.Kí alaafia máa wà ní Israẹli.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 128