Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 122:3-9 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí a kọ́,tí gbogbo rẹ̀ já pọ̀ di ọ̀kan.

4. Níbi tí àwọn ẹ̀yà,àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ,láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWAgẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli.

5. Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí,àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi.

6. Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu!“Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ!

7. Kí alaafia ó wà ninu rẹ,kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.”

8. Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi,n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.”

9. Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa,èmi óo máa wá ire rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 122