Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 120:2-7 BIBELI MIMỌ (BM)

2. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn èké,ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn.

3. Kí ni a óo fi san án fun yín?Kí ni a óo sì ṣe si yín, ẹ̀yin ẹlẹ́tàn?

4. Ọfà mímú ni a óo ta yín,a óo sì dáná sun yín.

5. Mo gbé! Nítorí pé mo dàbí àlejò tó wọ̀ ní Meṣeki,tí ń gbé ààrin àwọn àgọ́ Kedari.

6. Ó pẹ́ jù tí mo tí ń bá àwọn tí ó kórìíra alaafia gbé.

7. Alaafia ni èmi fẹ́,ṣugbọn nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ìjà ṣá ni tiwọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 120