Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:98-112 BIBELI MIMỌ (BM)

98. Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.

99. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.

100. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.

101. N kò rin ọ̀nà ibi kankan,kí n lè pa òfin rẹ mọ́.

102. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,nítorí pé o ti kọ́ mi.

103. Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ,ó dùn ju oyin lọ.

104. Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye,nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké.

105. Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi,òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi.

106. Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ,pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́.

107. Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ,sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

108. Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA,kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

109. Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo,ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ.

110. Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí,ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.

111. Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae,nítorí pé òun ni ayọ̀ mi.

112. Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo,àní, títí dé òpin.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119