Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:69-87 BIBELI MIMỌ (BM)

69. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.

70. Ọkàn wọn ti yigbì,ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.

71. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.

72. Òfin rẹ níye lórí fún mi,ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.

73. Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi,fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ.

74. Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùnnígbà tí wọ́n bá rí mi,nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

75. OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà,ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú.

76. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu,gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ.

77. Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè,nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi.

78. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga,nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí;ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.

79. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá,kí wọ́n lè mọ òfin rẹ.

80. Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,kí ojú má baà tì mí.

81. Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

82. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?”

83. Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

84. Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó?Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi?

85. Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.

86. Gbogbo òfin rẹ ló dájú;ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi.

87. Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé,ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119