Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:63-73 BIBELI MIMỌ (BM)

63. Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí,àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́.

64. OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

65. OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ,gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

66. Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.

67. Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ.

68. OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

69. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.

70. Ọkàn wọn ti yigbì,ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.

71. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.

72. Òfin rẹ níye lórí fún mi,ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.

73. Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi,fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119