Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:50-62 BIBELI MIMỌ (BM)

50. Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.

51. Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.

52. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.

53. Inú mi á máa ru,nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,tí wọn ń rú òfin rẹ.

54. Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,lákòókò ìrìn àjò mi láyé.

55. Mo ranti orúkọ rẹ lóru;OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:

56. Èyí ni ìṣe mi:Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.

57. OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́.

58. Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

59. Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,mo yipada sí ìlànà rẹ;

60. mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.

61. Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,n kò ní gbàgbé òfin rẹ.

62. Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́,nítorí ìlànà òdodo rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119