Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:46-53 BIBELI MIMỌ (BM)

46. N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,ojú kò sì ní tì mí.

47. Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀.

48. Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn,n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.

49. Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,èyí tí ó fún mi ní ìrètí.

50. Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.

51. Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.

52. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.

53. Inú mi á máa ru,nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,tí wọn ń rú òfin rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119