Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:162-171 BIBELI MIMỌ (BM)

162. Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ,bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun.

163. Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́,ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.

164. Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́nítorí òfin òdodo rẹ.

165. Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ,kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.

166. Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA,mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́.

167. Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́,mo fẹ́ràn wọn gidigidi.

168. Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ;gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí.

169. Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA,fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

170. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ,kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

171. Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ,pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119