Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:156-164 BIBELI MIMỌ (BM)

156. Àánú rẹ pọ̀, OLUWA,sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ.

157. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀,ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ.

158. Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra,nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́.

159. Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó!Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

160. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ,gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae.

161. Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí,ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn.

162. Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ,bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun.

163. Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́,ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.

164. Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́nítorí òfin òdodo rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119