Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:135-149 BIBELI MIMỌ (BM)

135. Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ;kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

136. Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò,nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́.

137. Olódodo ni ọ́, OLUWA,ìdájọ́ rẹ sì tọ́.

138. Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ,òtítọ́ patapata ni.

139. Mò ń tara gidigidi,nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.

140. A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin,mo sì fẹ́ràn rẹ̀.

141. Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi,sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

142. Òdodo rẹ wà títí lae,òtítọ́ sì ni òfin rẹ.

143. Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi,ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ.

144. Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae,fún mi ní òye kí n lè wà láàyè.

145. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́,OLUWA, dá mi lóhùn;n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.

146. Mo ké pè ọ́; gbà mí,n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ.

147. Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́;mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ.

148. N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru,kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ.

149. Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119