Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:128-145 BIBELI MIMỌ (BM)

128. Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ,mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.

129. Òfin rẹ dára,nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́.

130. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀,a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.

131. Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ,nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ.

132. Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóorebí o ti máa ń ṣesí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ.

133. Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ,má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi.

134. Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan,kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.

135. Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ;kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

136. Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò,nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́.

137. Olódodo ni ọ́, OLUWA,ìdájọ́ rẹ sì tọ́.

138. Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ,òtítọ́ patapata ni.

139. Mò ń tara gidigidi,nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.

140. A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin,mo sì fẹ́ràn rẹ̀.

141. Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi,sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

142. Òdodo rẹ wà títí lae,òtítọ́ sì ni òfin rẹ.

143. Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi,ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ.

144. Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae,fún mi ní òye kí n lè wà láàyè.

145. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́,OLUWA, dá mi lóhùn;n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119