Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:112-124 BIBELI MIMỌ (BM)

112. Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo,àní, títí dé òpin.

113. Mo kórìíra àwọn oníyèméjì,ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.

114. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi,mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

115. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́.

116. Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè,má sì dójú ìrètí mi tì mí.

117. Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu,kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo.

118. O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀,nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn.

119. O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin,nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ.

120. Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ,mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ.

121. Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ,má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára.

122. Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ,má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára.

123. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ,ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ.

124. Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119