Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 119:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n,àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.

2. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́,tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

3. Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

4. O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́,

5. Ìbá ti dára tótí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ!

6. Òun ni ojú kò fi ní tì mí,nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.

7. N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́,bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ.

8. N óo máa pa òfin rẹ mọ́,má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.

9. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.

10. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.

11. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 119