Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 118:4-19 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”

5. Ninu ìpọ́njú, mo ké pe OLUWA,ó dá mi lóhùn, ó sì tú mi sílẹ̀.

6. Nígbà tí OLUWA wà pẹlu mi, ẹ̀rù kò bà mí.Kí ni eniyan lè fi mí ṣe?

7. OLUWA wà pẹlu mi láti ràn mí lọ́wọ́,nítorí náà, n óo wo àwọn tí wọ́n kórìíra mipẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun.

8. Ó sàn láti sá di OLUWA,ju ati gbẹ́kẹ̀lé eniyan lọ.

9. Ó sàn láti sá di OLUWA,ju ati gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè.

10. Gbogbo orílẹ̀-èdè dòòyì ká mi,ṣugbọn ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run!

11. Wọ́n yí mi ká, àní, wọ́n dòòyì ká mi,ṣugbọn ni orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run!

12. Wọ́n ṣùrù bò mí bí oyin,ṣugbọn kíá ni wọ́n kú bí iná ìṣẹ́pẹ́;ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run.

13. Wọ́n gbógun tì mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ ṣubú,ṣugbọn OLUWA ràn mí lọ́wọ́.

14. OLUWA ni agbára ati orin mi,ó ti di olùgbàlà mi.

15. Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun,ninu àgọ́ àwọn olódodo.“Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá.

16. A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga,ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!”

17. N ò ní kú, yíyè ni n óo yè,n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe.

18. OLUWA jẹ mí níyà pupọ,ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19. Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi,kí n lè gba ibẹ̀ wọlé,kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 118