Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 116:5-19 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA,aláàánú ni Ọlọrun wa.

6. OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́;nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí.

7. Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá,nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ.

8. Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú,o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé,o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú.

9. Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè.

10. Igbagbọ mi kò yẹ̀, nígbà tí mo tilẹ̀ wí pé,“Ìpọ́njú dé bá mi gidigidi.”

11. Mo wí ninu ìdààmú ọkàn pé,“Èké ni gbogbo eniyan.”

12. Kí ni n óo san fún OLUWA,nítorí gbogbo oore rẹ̀ lórí mi?

13. N óo mu ẹbọ nǹkan mímu wá fún OLUWA,n óo sì pe orúkọ rẹ̀.

14. N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA,lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.

15. Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA.

16. OLUWA, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́,iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, àní, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ.O ti tú ìdè mi.

17. N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ,n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA.

18. N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWAlójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀,

19. ninu àgbàlá ilé OLUWA,láàrin rẹ, ìwọ ìlú Jerusalẹmu.Ẹ máa yin OLUWA!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 116