Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 116:2-7 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Nítorí pé ó tẹ́tí sí mi,nítorí náà, n óo máa ké pè éníwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.

3. Tàkúté ikú yí mi ká;ìrora isà òkú dé bá mi;ìyọnu ati ìnira sì bò mí mọ́lẹ̀.

4. Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA,mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!”

5. Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA,aláàánú ni Ọlọrun wa.

6. OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́;nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí.

7. Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá,nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 116